Main Article Content
Àfihàn agbára èṣù nínú àsàyàn ewì ajẹméṣu The reflection of Èṣu’spPower in the selected Èṣù-related poetry
Abstract
Isé yìí ṣe àfihàn agbára Èṣù nínú ewì ajẹméṣù. Iṣẹ́ yìí tún ṣe ìtúpalẹ̀ bí agbára Èṣù ti ṣe jẹyọ nínú àṣàyàn ewì-ajẹméṣù pàápàá jùlọ ẹṣẹ-Ifá. A ṣe èyí pẹ̀ ḷú èrò láti ṣạ̀ làyé àgbékalẹ ̣̀ àti àkóónú ewì ajẹméṣù gẹ ̣́gẹ ̣́ bí ó ti ṣe wà nínú ẹsẹ Ifá àti àlàyé nípa àbùdá agbára Èṣù. Abala méjì ọ ̣̀ tọ ̣̀ọ ̣̀ tọ ̣̀ ní ọgbọ ̣́n ìṣèwádìí tí a lò nínú iṣẹ ̣́ yìí. Abala àkóḳ ọ́ ni a ti ṣe ìfòṛ òẉ ánilẹ́nu-wò fún àwọn Babaláwo, àwọn olùsìn Èṣù àti àwọn apohùn ìbílẹ ní ìpínlẹ ̣̀ Ọ̣̀ṣun àti Ọ̣̀yọ ̣́ . Ìdí tí a fi ṣe àṣàyàn ìpínlẹ ̣̀ wọ ̣̀nyí ni pé, ibẹ ̣̀ ni a ti lè rí àwọn ìlú ìṣẹ ̣̀ǹbáyé tí a ti lè rí ewì ajeméṣù gbà ní ẹ̀ḳ únrẹ́ṛ ẹ́ .̣ Ní abala kejì ọgbọ ̣́n ìṣèwádìí yìí ni a ti yẹ òp̣ òḷọpọ̀ àwọn ìwé tí ó wúlò fún iṣẹ́ ìwádìí yìí wò bí i; àwọn ìwé Ifá, átíkù inú jọ́nà àti ìtàkùn àgbáyé. Àwọn àkójọ- èdè-fáyèẉ ò wòṇ yí ni a ṣe ìtúpalẹ̀ wọn pẹ ̣̀ lú tíóṛ ì àbùdá oníbejì. Àbájáde iṣẹ ̣́ yìí fi Èṣù hàn gẹ ̣́gẹ ̣́ bí Òrìṣà ti ó lágbára àyínìke àti àyínnìpadà, tí ó sì ń pè fún ìdájọ ̣́ òdodo àti àyípadạ̀ rere. dípò ojú aṣebi tí àwọn èsìn àjèjì fi wò ó. Iṣẹ́ yìí ṣe àfikún ìmọ ̣̀ tí ó ti wà nílẹ ̣̀ tẹ ̣́ lẹ ̣̀ lórí lítíréṣọ ̣̀ alohùn Yorùbá, ìmọ ̣̀ abínibí Yorùbá àti láti ṣe àtunṣe sí èrò àti ìgbàgbọ́ ̣ àwọn ẹ ̣̀sìn àjèjì nípa Èṣù.
This study examines the reflection of Èṣù’s power in the selected Èṣù-related poetry, analyzing how the deity's influence is embedded in the Yoruba oral poetry, most especially Ifá literary corpus. The research adopts both primary and secondary sources of data collection. The primary data were obtained through in-depth interviews with Ifá priests, Èṣù worshipers and traditional orature in Ọ̣̀ṣun and Ọ̣̀yọ ̣́ states, Southwestern Nigeria, to collect Èṣù-related poetry that encapsulates the power and role of Èṣù divinity. Secondary data were gathered from relevant Ifá texts, scholarly articles, and online resources. The collected data were transcribed and analyzed within the theoretical framework of binary complementarity, which emphasizes the dual yet interdependent nature of forces in literature, culture, and societal structures. Findings reveal that Èṣù embodies the principle of duality, functioning as both a positive and negative force -an agent of balance, mediation, and transformation within the esu-related poetry, especially Ifá literary tradition. This challenges colonial distortions that depict Èṣù as purely malevolent. The study contributes to the discourse on Yoruba oral literature, indigenous knowledge systems, and the nuanced reinterpretation of African religious traditions in contemporary scholarship.



